AGBA OLOṢELU TO N FOOGUN B’AWỌN ỌMỌ KEKEEKE LAṢEPỌ L’ABẸOKUTA TI DERO ẸWỌN O

Spread the love


Fun bi ọpọlọpọ wakati ni mọto ko fi raaye kọja lopopona ile ẹjọ Majisireeti to fikalẹ sagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta laarọ ana, ti i ṣe Fraide nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa, ti Zonal Intervention Squared (ZIS) foju baba agba radarada kan, Ọgbẹni Peter Ọdẹjimi to sọ pe agba oloṣelu loun, ẹni ti wọn lo n foogun bawọn ọmọ kekeeke tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtala lọ laṣepọ.

Lọsẹ to kọja lọ yi la gbọ pe aṣiri Peter Ọdẹjimi to ni agba oloṣelu nijọba ibilẹ ọdeda loun tu si AWIKONKO lọwọ, ta a si fa a le awọn ọlọpaa ZIS ti agbegbe Ọbada lọwọ pẹlu awọn aridaju fidio ti ko din ni mejila, nibi ti baba naa ti n bawọn ọmọ kekeeke yi laṣepọ.

Ko sibi ti iroyin Peter, ti wọn tun n pe ni Ọmọ Ọdẹ ko tan de niluu Abẹokuta ati agbegbe ẹ, to mu kawọn eeyan maa ṣepe nla-nla fun un. Ko si nnkan meji to mu ero pe jọ si kọọtu lọjọ Fraide ana, bi ko ṣe igba tiroyin kan pe yoo foju bale ẹjọ naa, ti wọn si fẹẹ wo oju ọdaran naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, pẹlu awọn fidio naa, kii ṣe awọn ọmọ kekeeke nikan ni Peter to n gbe lagbegbe Itẹsi mọ Ake n ba laṣepọ, o tun n bawọn iyawo ile sun, to fi mọ ọmọ to bi ninu ara rẹ sun.

Bakan naa lo tun n ba awọn ọmọ aburo rẹ tọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandinlogun sun. Bẹẹ la tun gbọ pe ọkan lara awọn ọmọ Peter to n jẹ Bamidele naa tun bimọ fun, tọmọ naa si ti n lọ pe ọdun mẹta bayii.

Lara awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe irẹsi ni Ọmọ Ọdẹ maa fi oogun sinu ẹ, ko too gbe e fawọn to ba fẹẹ ba sun lati lọọ jẹ ẹ, tawọn yẹn yoo si pada wa lati gba kinni abẹ ẹ sara.

Ọgbẹni Jamiu Arẹmu ti Peter n ba meji ninu awọn ọmọ ẹ sun naa ṣalaye baṣiri ṣe tu soun lọwọ, ati pe oun ko tete mọ afigba ti wọn fi fidio awọn ọmọ oun nibi ti baba yi ti n ko ibasun fun wọn lọwọ han oun loun too mọ.

Jamiu ṣalaye pe awọn ọmọ oun tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹjọ si mọkanla lawọn ọmọ oun mejeeji naa. O wa rawọ ẹbẹ pe kijọba gba oun nitori pe o ti ba aye awọn ọmọ oun jẹ kọja afẹnusọ.

Peter tọjọ ori ẹ din diẹ laadọrin (66-68years) ọdun nigba to n b’AWIKONKO sọrọ lẹyin taṣiri ẹ tu sọ pe “Kani mo mọ pe ẹnikan n ya fọnran mi ni, mi o ba ti na papa bora nitori pe mi o lero wi pe awọn eeyan n ṣọ mi ladugbo.

“Iṣẹ agbẹ ni mo n ṣe, bẹẹ ni mo tun n ṣe oṣelu, emi ni organizing secretary ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Ọdeda. Mo ti le lọgọta ọdun. Gẹgẹ bi awọn fidio ti mo wo yi, mi o le sọ pe irọ ni wọn pa mọ mi, mi o si le so pe ko ri bẹẹ, tori pe ẹri aridaju to ṣoju ṣaara ni. Ṣugbọn sibẹ, kii ṣe pe mo n fi okun fa ọmọ kankan wọnu yara ki n to ma a ba wọn laṣepọ.

“Nigba ti iyawo ko ba mi gbe, bi wọn ba wa sọdọ mi, ara mi le dide nibi ti wọn ti n ba mi ṣere, emi naa a si ba wọn ṣere. Bi ẹ ba wo awọn fidio naa daadaa, yatọ sawọn agbalagba yi, ẹ ko le ri mi pe gbogbo awọn ọmọ yi ni mo bọ ṣokoto bawọn sun.

“Abule wa to wa ni Itẹsi-Toba nijọba ibilẹ Ọdeda ni iyawo mi wa, ko ba mi gbe. Emi kọ ni mo bi Tunrayọ, ọmọ ẹgbọn mi ni, emi si kọ ni mo ṣe oyun fun Tunrayọ, igba ti mo fẹẹ muu lọ kọ iṣẹ ni wọn sọ pe ko le fi oyun kọ iṣẹ, mi o le sọ bo ṣe ṣe oyun naa. Mo maa n ba ṣere lẹẹkọọkan to ba rin si mi lara.

“Awọn ọmọ ti wọn ni mo n ba sun yi, kii ṣe pe mo maa n fun wọn lowo, ṣugbọn igba min in ti wọn ba wa sọdọ mi, ogun naira, ọgọrun ati igba naira ni mo maa n fun wọn, kii ṣe gbogbo igba ni mo n fun wọn, awọn naa kii beere owo. Gbogbo aye lo ri i pe mi o loogun fọmọ kankan ti wọn fi n wa sọdọ mi. Mi o ba iyawo adugbo sun, ita ni wọn ti n wa, mi o si foogun pe wọn.

“Emi kọ ni Bamidele bimọ fun, Ọpẹ lorukọ ẹni to fun Bamidele loyun, o si ti salọ latigba to ti fun un loyun. Tori pe emi ni mo ṣe ikomọ ọmọ naa lo jẹ ki n sọ ọ ni Temileyi, inu yara kan naa la jọ n gbe. Ọmọ odi ti mo ba sun yi lo wa sile mi, igba to wa, o jẹun, igba to jẹun tan lo ba mi ṣere, ti ara mi si dide, mo gbọ pe ọmọdun mẹsan ni odi yi.

“Patapata ẹ, pẹlu nnkan ti mo ṣe yi, wọn a sọ pe ki n lọ ṣẹwọn, ṣugbọn nnkan ti mo mọ daju ni pe mi o fipa mu awọn ọmọ yi, funra wọn ni wọn n wa bami ṣere.”

Adajọ ile ẹjọ naa ti wa a paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣi lọọ fi Peter ti wọn tun n pe ni Ọmọ Ọdẹ si ọgba ẹwọn ijọba to wa ni Ọba digba ti igbẹjọ min in yoo waye.

About Akingbade Mathew 2774 Articles
A certified Public relations practitioner, trained Journalist/Broadcaster, a Tv personality, A&R ,PR/Media consultant, Social Media Addict, it’s sure safe to say he is 100/% media and Entertainment. Also prolific Writer, Music/Entertainment expert with an Experience of over half a decade, and this has no doubt describe his persona in totality. He is referred by many as the skillful one with that million dollar idea or concept as well as marketing and selling it to the world. Email musicmobilng@gmail.com call/whatsapp +2348167999058

Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.


*