Erelu Kuti Kẹrin ti ilu Eko, Erelu Abiola Dosumu ti fesi lori ọrọ ọpa aṣẹ Ọba ilu Eko ti awọn janduku kan dede ji gbe kuro laafin lọjọru ọsẹ.

Spread the love

Erelu Kuti Kẹrin ti ilu Eko, Erelu Abiola Dosumu ti fesi lori ọrọ ọpa aṣẹ Ọba ilu Eko ti awọn janduku kan dede ji gbe kuro laafin lọjọru ọsẹ.

O ni ootọ ni pe inu n bi gbogbo eniyan lọwọ ni Naijria ti ilu si n gbona janjan ati pe o n ya awọn eeyan lara lati sọ bi nkan ṣe ri lọkan wọn.

Erelu Kuti mẹnu le ọrọ yii lori eto ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan kan nibi to ti sọrọ tẹdun tẹdun bi abiyamọ.

“Gẹgẹ bi iya ati ipo mi, mo ti parọwa si awọn to gbe ọpa aṣẹ lọ, o si da mi loju pe ẹni to gbe e lọ yoo pada wa tuba funrarẹ, yoo gbe pa aṣẹ naa wa yoo si tọrọ aforiji”.

Erelu ni lai ṣe jagidijagan ni naa ni yoo fẹsẹ ara rẹ rin wa lati da ọpa aṣẹ naa pada. O ni “a o ni tọwọ ofin bọ o bẹẹ si ni ao ni pa awọn ọmọ wa ṣugbọn mo n fi daa yin loju wipe iranti ati agbara awọn alalẹẹlẹ yoo dari rẹ pada wa”.

Ki gbogbo nkan to da bi o ṣe da yii, omi alafia ni wọn fi wẹ ilu Eko ti ipẹtu saawọ si maa n waye lai ni wahala, o ni alafia ọhun naa si ni yoo pada jọba ti awọn ọdọ to ṣe iṣẹ laabi naa yoo fi pada wa bẹbẹ.

Erelu ni eyi fihan gbangba pe awọn gẹgẹ bii adari ati obi ti kuna ninu iṣe wọn eyi tawọn si gbudọ dide tara ṣaṣa si.

Ṣe ọpa aṣẹ gangan ni wọn ji gba abi gbarọgudu?

Erelu Kuti ṣalaye pe Ọpa aṣẹ ti Ọba tuntun yatọ si ọpa aṣẹ amurode. O ni Ọpa aṣẹ eyi ti wọn maa n gbe le ọba tuntun to ba ṣẹṣẹ jẹ lọwọ kii dede si larọwọto araalu.

“Aabo to daju wa fun ọpa aṣẹ gidi. Ọpa aṣẹ amurode ni Ọba maa n gbe kaakiri eyi si ni eyi ti awọn janduku ri gbe lọ”.

Amọ sibẹ sibẹ Erelu ni oun ri bi awọn ọdọ naa ṣe n sọrọ pẹlu ibinu oun si ni imọlara rẹ gẹgẹ bi iya tori bi eeyan ba n ba ọmọ sọrọ, o ni iru esi to yẹ keeyan ri.

“Nigba tẹẹ ba ri ọmọ ọdun mẹtalelogun to kan dede joko, ko ṣiṣẹ, ko sabọ, ko lọ ileewe, ẹ o ti mọ pe nkan ti yiwọ”.

O ni laarin oṣu mẹta, ni kiakia, ijba ati awọn adari ipinlẹ Eko gbudọ ṣeto nkan ti wọn lee ṣe lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ toripe wọn o le gbọ nkankan ti awọn n sọ bayii.

RELATED:  #Headies2019: Headies Awards 2019 Full Winners List (Full List)

“Mo rii bi oju awọn ọdọ naa ṣe pọn rẹrẹ fun ibinu to si jẹ pe kii ṣe gbogbo wọn ni oniwa jagidijagan. Atiraka lo pọ ninu wọn. Tori naa ilana ati wa na abayọ si eyi gbudọ jẹ eyi to gbe iwa obi soju”.

Ìdílé ọba Akinsemoyin fáwọn jàǹdùkú lọ́jọ́ kan péré láti dá ọ̀pá àṣẹ tí wọn gbé padà

“Apena fẹ́gbẹ́ Oṣugbo, Opa, Akala àtẹ̀yin awo, ẹ wa ọ̀pá àṣẹ Ọ́ba Akiolu jáde”

Idile ọba Akinsemoyin ti Lagos Island ti dide si ọrọ ọpa asẹ Ọba Eko, Rilwan Akiolu ti awọn janduku kan ji gbe lọ lọjọru.

Saaju la ti sọ fun yin pe awọn janduku naa ya bo aafin ọba Akiolu lasiko isede tijọba ipinlẹ Eko kede rẹ tori iwọde EndSARS to di rogbodiyan.

Awọn janduku naa si lo gbe ọpa asẹ, bata, owo ati eroja ounjẹ lọ ninu aafin ọba naa, koda, wọn ba aafin ọhun jẹ kanlẹ, to fi mọ adagun omi iwẹ ọba, taamọ si swimming pool.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nibayi, idile Akinsemoyin, ti ọba Akiolu ti jade wa, ti wa ke fewe ọmọ mọ awọn janduku ti ọpa asẹ naa wa lọwọ wọn lati da pada lẹyẹ o sọka.

Bakan naa ni wọn n sekilọ pe, tawọn janduku naa ba kọ eti ọgbọin si ikilọ naa, lai da asẹ ọba pada, ohun ti oju wọn ba ri, ki wọn fara mọ.

Atẹjade kan ti idile ọba Akinsemoyin fisita lori isẹlẹ naa, eyi ti Ọmọọba Salami-Abisako ati Ọmọọba Adeyemi Sarumi fọwọsi, wa fun awọn jandukan naa ni ọjọ kansoso pere lati da ọpa asẹ pada sinu aafin.

Wọn ni ti wọn ko ba tẹle ikils naa, omi le tẹyin wọ igbin lẹnu fun wọn.

Idile ọba Akinsemoyin sisọ loju rẹ pe, oun wa lẹyin iwọde EndSARS naa nibẹrẹ pẹpẹ lati tako ifiyajẹni ati ipani nipakupa latọwọ awọn agbofinro wa, toun si bu ẹnu atẹ lu ni gbogbo ọna.

Amọ, o ni bi iwọde naa se yiwọ buru jai, toun si koro oju si pẹlu.

Atẹjade naa wa kesi Apena fẹgbẹ awo Osugbo, Opa, Akala atawọn olori alawo miran pẹlu awọn eeyan to di asa ilẹ wa mu, lati tete sawari ọpa asẹ ọba Akiolu, ki oju ma ba ti itẹ ọba.

Wo nnkan ti yoo ṣẹlẹ si Ọba ti wọ̀n ba gbe ọpa aṣẹ rẹ lọ:

Ni Ọjọru ọsẹ yii ni awọn janduku kan ya wọ aafin Ọba Isalẹ Eko, Ọba Rilwan Akiolu, to wa ni adugbo lasiko rogbodiyan to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Eko nitori iwọde EndSARS.

RELATED:  Ex-Playboy model Simone Holtznage, warn women against the danger of breast enlargement surgery

Yatọ si pe awọn janduku naa ba nkan jẹ ninu aafin naa, ni ṣe ni wọn tun ji ọ̀pá àṣẹ ọba gbe lọ.

Ohun to daju ni pe, nkan pataki ni ọ̀pá àṣẹ jẹ fun ọba nilẹ Yoruba, eyi si lo mu ki BBC Yoruba ba awọn onimọ nipa àṣà ati ìṣe ilẹ Yoruba sọrọ.

Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ati Alagba Peter Fatomilola, panupọ sọ pe, ọ̀pá àṣẹ ọba kii ṣe ohun amusere.

Ninu ọrọ ti ẹ, Alagba Fatomilola sọ pe, ọba ti ko ba ri ọ̀pá àṣẹ dabi pe ọba naa ti sọ ipo rẹ nu ni, ọgbẹni lasan si ni.

O ni nilẹ Yoruba, ọba ti ọ̀pá àṣẹ ba ra mọ lọwọ, boya wọn ji lọ ni o, tabi nitori nkan miran, kii ṣe ọba mọ, idi ni pe, ọ̀pá naa lo fi n pasẹ fun gbogbo ilu to jẹ ọba le l’ori.

Ni ero ti ẹ, Oloye Elebuibon sọ pe aṣẹ lọba ma n pa, ọba kii daba, nitori ọ̀pá to wa lọwọ rẹ, idi si niyii ti wọn fi ma n pe ọba ni alasẹ ikeji òrìṣà.

O fi kun ọrọ rẹ pe, o ṣe ni laanu pe iru iṣẹlẹ naa waye, paapa nilẹ Yoruba.

“Nkan to buru pupọ ni awọn to ji ọ̀pá àṣẹ gbe ṣe, nitori pe ko yẹ ki a maa fi awọn ọba wa wọlẹ.

Ibi ọwọ, ibi àṣẹ ni aafin ọba, kii ṣe ile igbafẹ, nitori pe ibi ti wọn n ko awọn nkan isẹnbaye pamọ si ni.

Ọba to ba jẹ ni ibikibi nilẹ Yoruba, to si ṣe gbogbo oro ati awọn nkan to yẹ ko ṣe ko to o di ọba, kii ṣe eeyan lasan mọ, o ti di òrìṣà.”

Kinni yoo sẹlẹ si ọba tabi ilu ti wọn ji ọ̀pá àṣẹ rẹ gbé salọ?

Alagba Peter Fatomilola sọ pe, to ba jẹ pe laye àtijọ́ ni, gbogbo ilu yoo sọ pe ki ọba naa wa a lọ nitori pe kii ṣe oun lo ni i, fun gbogbo ọba to ba jẹ ni.

“Wọn si tun le ṣe etutu lati mu ki ẹni to ji ọ̀pá da a pada tabi ki ọ̀pá àṣẹ fi ẹsẹ ara rẹ rin wa.”

Oloye Elebuibon ni ti ẹ sọ pe, ẹni to lọ ọ gbe ọ̀pá àṣẹ ọba ni isalẹ Eko “ti fi ara rẹ ṣepe lai mọ”.

RELATED:  OMG!! How Childless Woman Was Beaten And Burnt To Death For Stealing Baby In Hospital

Peter Fatomilola ní ‘Ọ̀gbẹ́ni’ lásán ni ọba tí kò rí ọ̀pá àṣẹ rẹ̀

O ṣalaye pe etutu ni wọn o ṣe lati ri ọ̀pá àṣẹ naa, ati lẹyin ti wọn ba da a pada tan, ki gbogbo nkan le tuba, ko le tu ṣẹ.

“Awọn to ji ọ̀pá àṣẹ ọba fi tabuku ọba naa ni.

Wọn fẹ ki ọba naa wa lai ni àṣẹ, ọ̀wọ̀ ati agbara.

Oun naa si gbọdọ gbe gbogbo igbesẹ lati da awọn nkan naa pada.”

Fatomilola fikun pe, Peter Fatomilola ní ‘Ọ̀gbẹ́ni’ lásán ni ọba tí kò rí ọ̀pá àṣẹ rẹ̀’ nitori ko ni asẹ lẹnu mọ.

Kilo le fa a ti awọn araalu ko fi le daabo bo ọba tabi ma a wo debi pe awọn janduku n wọ ààfin gbe ọ̀pá?

Lori ibeere yii, Fatomilola sọ pe oye to lagbara ni ipo ọba laye atijọ, sugbọn awọn ọba ode oni ko lẹnu ọrọ mọ, nitori pe oloṣelu lo n fi wọn joye.

“Awọn oloṣelu lo ni àṣẹ bayii, kii ṣe ọba mọ. Oloṣelu ma n ba awọn ọba wi bi ọmọ ọdọ, awọn ọba ti sọ ara wọn di yẹ̀bù-yẹ́bù, awọn oloṣelu naa si ti ba àṣà wa jẹ.”

Elebuibon ni “ejo ọrọ naa lọwọ ninu, nitori pe olè ile lo n ṣilẹkun fun ti ode, bakan naa lo sọ pe eyi fihan pe awọn ọta ti wa ni ayika ọba.”

Njẹ awọn janduku ti gbe ọ̀pá àṣẹ ọba ri nilẹ Yoruba?

Oloye Yemi Elebuibon sọ pe, o ti ṣẹlẹ ri, àmọ́ kii ṣe lati ọwọ awọn janduku.

O ni o ma a n ṣẹlẹ, paapa ti wọn ba fẹ ẹ sọ agbara iru ọba bẹ ẹ di yẹpẹrẹ, nitori pe o kọ lati ṣe awọn nkan to yẹ ko ṣe, boya ìrúbọ tabi nkan míì, tabi to ba n ṣe aigbọran.

Sugbọn kii ṣe bi i ki awọn janduku rọ́ wọ aafin.

About Akingbade Mathew 3129 Articles
A certified Public relations practitioner, trained Journalist/Broadcaster, a Tv personality, A&R ,PR/Media consultant, Social Media Addict, it’s sure safe to say he is 100/% media and Entertainment. Also prolific Writer, Music/Entertainment expert with an Experience of over half a decade, and this has no doubt describe his persona in totality. He is referred by many as the skillful one with that million dollar idea or concept as well as marketing and selling it to the world. Email musicmobilng@gmail.com call/whatsapp +2348167999058

Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.


*